Àrànmọ́
Àrànmọ́ ni agbára tí ìró kan ní lórí òmíràn, èyí tí ó lè farapẹ́ kí ìró méjèèjì yí padà di irú kan náà.[1] Nígbà tí ìró kan bá yí padà láti fara jọ ìró mìíràn, irú ìyípadà báyìí ni a ń pè ní àrànmọ́. Ìró tí ó yí padà ní agbàrànmọ́, ìró tí ó mú kí èkejì gba àrànmọ́ ni afàrànmọ́. Oríṣi àrànmọ́ ló wà àrànmọ́ lè jẹ́ ti fáwẹ̀lì tàbí ohùn.[2]
Àrànmọ́ ohùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àrànmọ́ ohùn ni ìyípadà ohùn kan láti fara jọ ohùn mìíràn.[3] Bí àpẹẹrẹ;
- Ohùn òkè ràn mọ́ ohùn àárín
Eégún - éégún
Oókan- óókan
- Ohùn ìsàlè ràn mọ�� ohùn òkè
Ọ̀wọ́ Ọ̀wọ́ - ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
èló èló - èlèèló
Àrànmọ́ fáwẹ̀lì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àrànmọ́ fáwẹ̀lì ni ìyípadà fáwẹ̀lì kan láti fara jọ fáwẹ̀lì mìíràn. F¹ + F²= F¹ tàbí F¹ + F²= F² +
BÍ àpẹẹrẹ
Owó iṣẹ́- owóoṣẹ́
Ìyá ẹgbẹ́ - iyẹ́ẹgbẹ́
Àrànmọ́ fáwẹ̀lì máa ń jẹ yọ nínú àwọn ẹ̀hun wọ̀nyí.
- Ọ̀rọ̀ - orúkọ àti ọ̀rọ̀ - orúkọ
Ilé ilẹ́ - ilẹ́elẹ́
- Ọ̀rọ̀ ìṣe - ọ̀rọ̀ọ̀sẹ
Àlàyé : kìí ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ orúkọ ni a máa ń ṣe àrànmọ́ fún
B. A
Adé ọba - adọ́ọba
Ijó agbo - ijáagbo
- Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ orúkọ gẹ́gẹ́ bíi Olùwà àti Atọ́ka ìyísódì. B.a
Ẹ ò lọ - ẹ ẹ̀ lọ
Wọn ò lọ - wọn - ọ̀n lọ
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Definition of ASSIMILATION". Merriam-Webster. 2023-10-23. Retrieved 2024-07-19.
- ↑ Pauls, Elizabeth Prine (1998-07-20). "Definition, History, & Facts". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2024-07-19.
- ↑ Fonọ́lọ́jì àti gírámà Yorùbá - Ayọ̀ Bámgbóṣé; ISBN 978 030 155 0