Jump to content

Ìpínlẹ̀ Èkìtì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ipinle Ekiti)
Ìpínlẹ̀ Èkìtì
Nickname(s): 
Location of Ekiti State in Nigeria
Location of Ekiti State in Nigeria
Country Nigeria
Date created1 October 1996
CapitalAdo Ekiti
Government
 • Governor
(List)
Kayode Fayemi [1]
Area
 • Total6,353 km2 (2,453 sq mi)
Area rank31st of 36
Population
 • Estimate 
(2005)
2,737,186
 • Rank29th of 36
GDP (PPP)
 • Year2007
 • Total$2.85 billion[2]
 • Per capita$1,169[2]
Time zoneUTC+01 (WAT)
ISO 3166 codeNG-EK

Ìpínlẹ̀ Èkìtì jẹ́ Ìpínlè ní apá ìwọ̀ oòrùn Nàíjíríà tí ó jẹ́ dídásílẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù ọwàwà,1996 pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ tuntun márùn-rún mìíràn látọwọ́ ọ̀gágun Sani Abacha.

Èkìtì ti jẹ́ ìpínlẹ̀ olómìnira kí àwọn òyìnbó tó dé. Èkìtì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìpílẹ̀ Yorùbá ní ibi tí a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní òní. Àwọn ará Èkìtì jẹ́ àwọn tí a lè tọpasẹ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà, bàbá àti babańlá ìran Yorùbá.[3]

Èrò méjì lówà nípa ìtàn Èkìtì. Àkọ́kọ́ ni èyí tí ó so Èkìtì mọ́ Ilé-Ifẹ̀. Ìtàn náà sọ pé Ọlọ́fin, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Odùduwà tí ó bí ọmọ mẹ́rìndílógún. Nípa pé wọ́n ń wá ilẹ̀ mìíràn láti gbé, wọ́n kúrò ní Ilé-Ifẹ̀ wọ́n sì pọ̀ sókè rajà. Wọ́n gba Iwò- Elérú ní Isarun wọ́n sì ní láti dúró síbì kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Igbó-Aka tí kò jìnà sí Ile-Oluji.[4]

Ọlọ́fin àti àwọn ará rẹ̀ tẹ̀síwájú nínú ìrìn-àjò wọn, Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Ọwá-Obòkun (Ọba ilẹ̀ Ijẹṣà) Orangun tí ó jẹ́ ọba Ìlá pinnu láti dúró sí ibi tí à ń pè nih Ìjẹ̀ṣà ní òní àti Igbomina ní ìpínlẹ̀ Osun.[5] Àwọn ọmọ mẹ́rìlá yòókù tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjọ̀ wọn, wọ́n sì gúlẹ̀ sí ibi tí a mọ̀ sí Èkìtì ní òní. Wọ́n ṣe àkíyèsi pé òkè pọ̀ ní ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí wọ́n sì pe ibẹ̀ ní 'ilẹ̀ olókìtì' èyí tí ó padà di Èkìtì, báyìí ni Èkìtì ṣe gba orúkọ.Àdàkọ:Cn

Èrò kejì nípa orísun Èkìtì ni pé Odùduwà tó jẹ́ babańlá ìran Yorùbá rin ìrìn-àjò lọ sí Ilé-Ifẹ̀, ó ri pé àwọn kan ti tẹ̀dó sí ibẹ̀. Lára àwọn olórí tí ó bá níbẹ̀ ni Agbonniregun, Obatala, Orelure, Obameri, Elesije, Obamirin, Obalejugbe, ká mẹ́*** ba díẹ̀ nínú wọn. Ohun tí ìtàn sọ nipé àwọn àrọ́mọdọ́mọ Agbọnniregun ni wọ́n wà ní Èkìtì, àpẹẹrẹ ni Alara àti Ajero tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ifá. Orunmila [Agbonniregun] gan-gan fún ra ẹ̀ gbé púpọ̀ ayé rẹ̀ ní Adó ìdí nìyín tí wọ́n fi máa sọpé 'Adó ni ilé-Ifá' . Àtìgbà náà ni àwọn ará Èkìtì tih wà níbi tí wọ́n wà dì ọ̀ní.[6]

Kò sí ẹni tí ó lè sọ pàtó ìgbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀, ìdí ni pé ìmọ̀ mọ̀-ọ́-kọ-mọ̀-ó-kọ̀ ò tí ì dé nígbà náà, ohun kan tí ó dájú tádàá ni pé àwọn èèyàn ti ń gbé ní Èkìtì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ìtàn jẹ́ kí a mọ̀ pé àwọn ọba Èkìtì ní ọlá nígbà ayé wọn ní sẹ́ńtúrì kẹtàlá. Àpẹẹrẹ ni Ewi Ata ti Ado-Ekiti ní ọdún.

Gòmìnà ìpínlè Èkìtì nì Biodun Oyebanji

  1. "Ekiti State, Nigeria Genealogy". FamilySearch Wiki. 2020-04-11. Retrieved 2022-03-22. 
  2. 2.0 2.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20. 
  3. "About Ekiti State" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-07-12. Retrieved 2021-07-12. 
  4. "How The Ara People Of Ekiti Committed Mass Suicide To Avoid Enslavement". Spread.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-23. Archived from the original on 2021-07-12. Retrieved 2021-07-12. 
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02
  6. "Ekiti Kete - Canada". Archived from the original on 2013-07-17. Retrieved 2018-02-14.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)